About me

Oriki

Oriki Idile Baba

Aduke Ako, Omo Soganmo n’iju, Omo Aiye gbotola, obere Omo amowo Ila ra eru, Omo amowo boobo ra gbayi, owo lamu monlu oka gbe, Omo owo miwaale, oka mii hu seesese, megun moosi Omo onita ajiwarii, b’eru baji a wa tie, B’iwofa baji a wa tie, Siyana oto, Emi na o tete ji, m’alo wa temi n’ile baba to bi mi l’omo.

Omo Onigun nila, omo alahere owo, omo alale ki won to lako, Owo lamu molu oka gbin loke’la, op’oke’la komo lagba ayona lowo, omo dabala osi oki p’okela koma ni gba ayonaa lowo, omo onigba’je, omo onigba aritaka, omo oni gba ewele.

Oriki Idile Iya Baba

Aduke, Omo onire osin, omo oba keyemo keyun kojoni bon yun, omo agbota lowo ojo, beki won ni Ire won oni je, beki won oni fun omo owu ni won fije ni Ire, modun omo abule sowo.

Aduke Ako, sun re, o di gbere o.